Ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo to kalẹ silu Ogbomosos ti wọgile iyansipo Soun tuntun fun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Olaoye.
Ijọba ipinlẹ Oyo lo kede Pasitọ Ghandi Olaoye gẹgẹ bi Soun tuntun ti awọn afbajẹ ilu naa si fi jẹ ọba lọjọ Kẹjọ osu Kẹsan dun 2023.
Saaju asiko yii ni ọmọ oye miran, ti wọn dijọ n du ipo Soun, Kabir Laoye ti pe ẹjọ pe Ghandi Olaoye ko lẹtọ lati du ipo Soun.
Ile ẹjọ si pasẹ nigba naa pe ijọba ipinlẹ Oyo ko gbọdọ yan ẹnikẹni sipo naa, titi ti oun yoo fi gbe idajọ oun kalẹ.
Amọ ikede jade sita pe ijọba ipinlẹ Oyo ti yan Pasitọ Ghandi Laoye bii Soun tilẹ Ogbomoso tuntun.
Kí ló dé tí adájọ́ fi wọ́gilé ìyànsípò Soun tuntun?
Ọmọọba Kabir Olaoye to pe ẹjọ lati tako iyansipo Ghandi salaye pe aise deede wa ninu ilana ti wọn fi yan an.
O wa n rọ ile ẹjọ giga naa lati wọle iyansipo ọba tuntun yii, ko si pasẹ fun awọn afọbajẹ lati bẹrẹ igbesẹ yiyan ọmọ oye miran.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Adedokun to n gbọ ẹjọ naa wa kede pe iyansipo ọba Laoye ko bofinmu.
Bakan naa lo pasẹ pe ki awọn afọbajẹ lọ bẹrẹ ilana ọtun lati yan Soun tuntun
Saaju ni Adajọ Adedokun ti wọgile ẹbẹ mẹta ti ọkan ninu awọn olupẹjọ, Ọmọọba Adeyemi Taofiq Akorede Laoye gbe siwaju rẹ.
Awọn ẹbẹ naa loun naa fi n pe iyansipo oriade tuntun naa nija.
A maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.
Source: BBC Yoruba
Add Comment