Aláàfin Ọ̀yọ́ Ikú bàbá yeye, Igbákejì orisa Ọmọ a jowu yọ kọ lẹnu A bi Ila tọ-tọ lẹhin Pan-du-ku bi soo ro Ibi ti wọn ti ni ki Olowo gbowo Ki Iwọfa sọ tọ wọ rẹ nu, Ṣe ko le ba di’ ja, ko le ba di apọn Ki Ọba Alade le ri n jẹ, Ọyọ mọ l’ afin Ojo pa Ṣẹkẹrẹ, ọmọ Atiba Babalawo lo d’ fa, pe ibiti ilẹ gbe yọ ni aye wọn, Ọyọ ode oni, ni Agọ-Oja, Ọba lo tun tẹ, laye Atiba Ọba, Adebinpe OSakẹkẹ, Adebinpe, eji ọgbọrọ, Alade lẹyẹ Akande, Ọba, aji bo ‘yinbo se le ri, Omo Ikú, tí Ikú o gbodo pa Omo àrùn, ti àrùn o gbodo se Omo ofo, t’ofo ko le se Atanda l’o gbin agbado oran S’ehinkule elehinkule Elehinkule ko gbodo yaa je Beeni ko si gbodo tu u danu Ọba taa ri, taa ka po la po, taa kọ fa, lọ fa, Taa ka pata,lo ri Apata, Bẹmbẹ n ro, imulẹ lẹhin agbara, Ọdọfin ijaye,o jẹ du ro de la kanlu, ọmọ a ja ni lẹ ran gan-gan, Eji ọgbọrọ, Alaafin Atiba, Ọba lo ko wo jẹ, Ko to do ri Ọba to wa lo ye, A ji se bi Ọyọlaa ri, Ọyọ O jẹ se bi baba eni kan-kan Pin ni si lọ ‘mọ Erin t’ n fọ la ya ‘gi, Ọyọ lo ni ka rin, ka san pa, ka gbẹsẹ, ko yẹ yan, Oko ala kẹ, ọmọ a fo ko ra lu, ti wọn o ba mọ Erin, Se wọn o gbọ‘hun Erin ni, A ji sọ la, ọmọa jo wu yọ kọ lẹ nu. Lamidi Oba, baba e Oba Alaafin Oyo, a mi ogorun meji ota iban bi eni n mi oka-amala dudu Alaafin Lamidi Adeyemi, omo Alaafin Adeniran Adeyemi ijosi Erin wo, Àjànàkú sùn bi òkè
Oyo Affairs is an independent news media with the main focus on Oyo state news, politics, current events, trending happenings within and around Oyo state, Nigeria
Add Comment